1. Kro 24 YCE

Iṣẹ́ Àwọn Àlùfáà

1 NJẸ bi a ti pín awọn ọmọ Aaroni ni wọnyi. Awọn ọmọ Aaroni; Nadabu ati Abihu, Eleasari, ati Itamari.

2 Ṣugbọn Nadabu ati Abihu kú ṣaju baba wọn, nwọn kò si li ọmọ: nitorina ni Eleasari ati Itamari fi ṣiṣẹ alufa.

3 Dafidi si pin wọn, ati Sadoku ninu awọn ọmọ Eleasari, ati Ahimeleki ninu awọn ọmọ Itamari, gẹgẹ bi iṣẹ wọn ninu ìsin wọn.

4 A si ri awọn ọkunrin ti o nṣe olori ninu awọn ọmọ Eleasari jù ti inu awọn ọmọ Itamari lọ, bayi li a si pin wọn. Ninu awọn ọmọ Eleasari, ọkunrin mẹrindilogun li o nṣe olori ni ile baba wọn, ati mẹjọ ninu awọn ọmọ Itamari, gẹgẹ bi ile baba wọn.

5 Bayi li a fi iṣẹkeké pin wọn, iru kan mọ ikeji pẹlu; nitori awọn olori ibi mimọ́, ati olori ti Ọlọrun wà ninu awọn ọmọ Eleasari, ati ninu awọn ọmọ Itamari.

6 Ati Ṣemaiah ọmọ Nataneeli akọwe, ọkan ninu awọn ọmọ Lefi kọ wọn niwaju ọba, ati awọn olori, ati Sadoku alufa, ati Ahimeleki, ọmọ Abiatari, ati niwaju olori awọn baba awọn alufa, ati awọn ọmọ Lefi: a mu ile baba kan fun Eleasari, a si mu ọkan fun Itamari.

7 Njẹ iṣẹkeké ekini jade fun Jehoiaribu, ekeji fun Jedaiah,

8 Ẹkẹta fun Harimu, ẹkẹrin fun Seorimu,

9 Ẹkarun fun Malkijah, ẹkẹfa fun Mijamini,

10 Ekeje fun Hakkosi, ẹkẹjọ fun Abijah,

11 Ẹkẹsan fun Jeṣua, ẹkẹwa fun Ṣekaniah,

12 Ẹkọkanla fun Eliaṣibu, ekejila fun Jakimu,

13 Ẹkẹtala fun Huppa, ẹkẹrinla fun Jeṣebeabu,

14 Ẹkẹdogun fun Bilga, ẹkẹrindilogun fun Immeri,

15 Ẹkẹtadilogun fun Heṣiri, ekejidilogun fun Afisesi,

16 Ẹkọkandilogun fun Petahiah, ogun fun Jehesekeli,

17 Ẹkọkanlelogun fun Jakini, ekejilelogun fun Gamuli,

18 Ẹkẹtalelogun fun Delaiah, ẹkẹrinlelogun fun Maasiah.

19 Wọnyi ni itò wọn ni ìsin wọn lati lọ sinu ile Oluwa, gẹgẹ bi iṣe wọn nipa ọwọ Aaroni baba wọn, bi Oluwa Ọlọrun Israeli ti paṣẹ fun u.

Orúkọ Àwọn Ọmọ Lefi

20 Iyokù awọn ọmọ Lefi ni wọnyi: Ninu awọn ọmọ Amramu; Ṣubaeli: ninu awọn ọmọ Ṣubaeli; Jehediah.

21 Nipa ti Rehabiah; ninu awọn ọmọ Rehabiah, ekini Iṣṣiah.

22 Ninu awọn Ishari; Ṣelomoti; ninu awọn ọmọ Ṣelomoti; Jahati.

23 Awọn ọmọ Hebroni: Jeriah ikini; Amariah ekeji, Jahasieli ẹkẹta, Jekamamu ẹkẹrin.

24 Awọn ọmọ Ussieli; Mika: awọn ọmọ Mika; Ṣamiri.

25 Arakunrin Mika ni Iṣṣiah; ninu awọn ọmọ Iṣṣiah; Sekariah.

26 Awọn ọmọ Merari ni Mali ati Muṣi: awọn ọmọ Jaasiah; Beno;

27 Awọn ọmọ Merari nipa Jaasiah; Beno ati Ṣohamu, ati Sakkuri, ati Ibri.

28 Lati ọdọ Mali ni Eleasari ti wá, ẹniti kò li ọmọkunrin.

29 Nipa ti Kiṣi: ọmọ Kiṣi ni Jerameeli.

30 Awọn ọmọ Muṣi pẹlu; Mali, ati Ederi, ati Jerimoti. Wọnyi li ọmọ awọn ọmọ Lefi nipa ile baba wọn.

31 Awọn wọnyi pẹlu ṣẹ keké gẹgẹ bi awọn arakunrin wọn awọn ọmọ Aaroni niwaju Dafidi ọba ati Sadoku, ati Ahimeleki, ati awọn olori awọn baba awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi: olori awọn baba gẹgẹ bi aburo rẹ̀.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29