15 Ati awọn ara Hifi, ati awọn ara Arki, ati awọn ara Sini,
16 Ati awọn ara Arfadi, ati awọn ara Semari, ati awọn ara Hamati.
17 Awọn ọmọ Ṣemu; Elamu, ati Assuri, ati Arfaksadi, ati Ludi, ati Aramu, ati Usi, ati Huli, ati Geteri, ati Meṣeki.
18 Arfaksadi si bi Ṣela; Ṣela si bi Eberi.
19 Ati fun Eberi li a bi ọmọkunrin meji: orukọ ọkan ni Pelegi; nitori li ọjọ rẹ̀ li a pin aiye niya: orukọ arakunrin rẹ̀ si ni Joktani.
20 Joktani si bi Almodadi, ati Ṣelefi, ati Hasarmafeti, ati Jera,
21 Ati Hadoramu, ati Usali, ati Dikla,