1 AWỌN ara Filistia si ba Israeli jagun, awọn ọkunrin Israeli si sá niwaju awọn ara Filistia, nwọn fi ara pa, nwọn si ṣubu li òke Gilboa.
2 Awọn ara Filistia si lepa Saulu kikan, ati awọn ọmọ rẹ̀: awọn ara Filistia si pa Jonatani, ati Abinadabu, ati Melkiṣua, awọn ọmọ Saulu.
3 Ogun na si le fun Saulu, awọn tafàtafà si ba a, on si damu nitori awọn tafàtafà.
4 Nigbana ni Saulu wi fun ẹniti o ru ihamọra rẹ̀ pe, Fa idà rẹ yọ, ki o si fi gun mi, ki awọn alaikọla wọnyi ki o má ba wá fi mi ṣẹsin. Ṣugbọn ẹniti o ru ihamọra rẹ̀ kọ̀, nitori ẹ̀ru ba a gidigidi. Bẹ̃ni Saulu si mu idà, o si ṣubu le e.
5 Nigbati ẹniti o ru ihamọra rẹ̀ si ri pe Saulu kú, on na pẹlu si ṣubu le idà rẹ̀, o si kú.