10 Nwọn si fi ihamọra rẹ̀ sinu ile oriṣa wọn, nwọn si kan agbari rẹ̀ mọ ile Dagoni.
11 Nigbati gbogbo Jabeṣ-gileadi gbọ́ gbogbo eyi ti awọn ara Filistia ti ṣe si Saulu,
12 Nwọn dide, gbogbo awọn ọkunrin ogun, nwọn si gbé okú Saulu lọ, ati okú awọn ọmọ rẹ̀, nwọn wá si Jabeṣi, nwọn si sìn egungun wọn labẹ igi oaku ni Jabeṣi, nwọn si gbawẹ ni ijọ meje.
13 Bẹ̃ni Saulu kú ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ti o da si Oluwa, nitori ọ̀rọ Oluwa, ti on kò kiyesi, ati pẹlu nitori o lọ bère ọ̀ràn lọwọ abokusọrọ, lati ṣe ibere.
14 Kò si bère lọwọ Oluwa; nitorina li o ṣe pa a, o si yi ijọba na pada sọdọ Dafidi ọmọ Jesse.