2 Ati pẹlu li atijọ, ani nigbati Saulu jẹ ọba, iwọ li o nmu Israeli jade ti o si nmu u wá ile: Oluwa Ọlọrun rẹ si wi fun ọ pe, Ki iwọ ki o bọ Israeli, enia mi, ki iwọ ki o si ṣe ọmọ-alade lori Israeli enia mi.
3 Nitorina ni gbogbo awọn agbagba Israeli ṣe tọ ọba wá ni Hebroni; Dafidi si ba wọn da majẹmu ni Hebroni niwaju Oluwa; nwọn si fi ororo yan Dafidi li ọba lori Israeli, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa nipa ọwọ Samueli.
4 Ati Dafidi ati gbogbo Israeli jade lọ si Jerusalemu, ti iṣe Jebusi; awọn Jebusi ara ilẹ na ngbe ibẹ̀.
5 Awọn ara ilu Jebusi si wi fun Dafidi pe, Iwọ kò gbọdọ wọ̀ ihinyi wa. Ṣugbọn Dafidi kó ilu odi Sioni ti iṣe ilu Dafidi.
6 Dafidi si wipe, Ẹnikẹni ti o ba tetekọ kọlù awọn ara Jebusi ni yio ṣe olori ati balogun. Bẹ̃ni Joabu ọmọ Seruiah si tetekọ gòke lọ, o si jẹ olori.
7 Dafidi si ngbe inu ilu odi, nitorina ni nwọn fi npè e ni ilu Dafidi.
8 O si kọ́ ilu na yikakiri; ani lati Millo yikakiri: Joabu si tun iyokù ilu na ṣe.