1 DAFIDI si ba awọn olori ogun ẹgbẹgbẹrun ati ọrọrun ati olukuluku olori gbèro.
2 Dafidi si wi fun gbogbo ijọ Israeli pe, Bi o ba dara loju nyin, bi o ba si ti ọwọ Oluwa Ọlọrun wa wá, jẹ ki a ranṣẹ kiri sọdọ awọn arakunrin wa ni ibi gbogbo, ti o kù ni gbogbo ilẹ Israeli, ati pẹlu wọn si alufa ati awọn ọmọ Lefi ti mbẹ ni ilu agbegbe wọn, ki nwọn ki o le ko ara wọn jọ sọdọ wa:
3 Ẹ jẹ ki a si tun mu apoti ẹri Ọlọrun wa wa si ọdọ wa: nitoriti awa kò ṣafẹri rẹ̀ li ọjọ Saulu.
4 Gbogbo ijọ na si wipe, ẹ jẹ ki a ṣe bẹ̃: nitori ti nkan na tọ loju gbogbo enia.
5 Bẹ̃ni Dafidi ko gbogbo Israeli jọ lati odò Egipti ani titi de Hemati, lati mu apoti ẹri Ọlọrun lati Kirjat-jearimu wá.
6 Dafidi si gòke ati gbogbo Israeli si Baala, si Kirjat-jearimu, ti iṣe ti Juda, lati mu apoti ẹ̀ri Ọlọrun Oluwa gòke lati ibẹ wá, ti ngbe arin Kerubimu, nibiti a npe orukọ Ọlọrun.