6 Dafidi si gòke ati gbogbo Israeli si Baala, si Kirjat-jearimu, ti iṣe ti Juda, lati mu apoti ẹ̀ri Ọlọrun Oluwa gòke lati ibẹ wá, ti ngbe arin Kerubimu, nibiti a npe orukọ Ọlọrun.
7 Nwọn si gbé apoti ẹri Ọlọrun ka kẹkẹ́ titun lati inu ile Abinadabu wá, ati Ussa ati Ahio ntọ́ kẹkẹ́ na.
8 Ati Dafidi ati gbogbo Israeli fi gbogbo agbara wọn ṣire niwaju Ọlọrun, pẹlu orin, ati pẹlu duru, ati pẹlu psalteri, ati pẹlu timbreli, ati pẹlu simbali, ati pẹlu ipè.
9 Nigbati nwọn si de ilẹ ipaka Kidroni, Ussa nà ọwọ rẹ̀ lati di apoti ẹri na mu; nitoriti awọn malu kọsẹ.
10 Ibinu Oluwa si ru si Ussa, o si lù, nibẹ li o si kú niwaju Ọlọrun.
11 Dafidi si binu nitori ti Oluwa ké Ussa kuro: nitorina ni a ṣe pè ibẹ na ni Peres-Ussa titi di oni.
12 Dafidi si bẹ̀ru Ọlọrun li ọjọ na wipe, Emi o ha ṣe mu apoti ẹri Ọlọrun wá sọdọ mi?