1 DAFIDI si kọ́ ile fun ara rẹ̀ ni ilu Dafidi, o si pese ipò kan fun apoti ẹri Ọlọrun, o si pa agọ kan fun u.
2 Nigbana ni Dafidi wipe, Ẹnikan kò yẹ lati rù apoti ẹri Ọlọrun bikoṣe awọn ọmọ Lefi; nitori awọn ni Oluwa ti yàn lati ma gbé apoti ẹri Ọlọrun, ati lati ma ṣe iranṣẹ fun u titi lai.
3 Dafidi si ko gbogbo Israeli jọ si Jerusalemu, lati gbé apoti ẹri Oluwa gòke lọ si ipò rẹ̀ ti o ti pese fun u.
4 Dafidi si pè awọn ọmọ Aaroni, ati awọn ọmọ Lefi jọ.
5 Ninu awọn ọmọ Kohati; Urieli olori, ati awọn arakunrin rẹ̀ ọgọfa:
6 Ninu awọn ọmọ Merari; Asaiah olori, ati awọn arakunrin rẹ̀ igba o le ogun: