13 Ẹnyin iru-ọmọ Israeli iranṣẹ rẹ̀, ẹnyin ọmọ Jakobu ayanfẹ rẹ̀.
14 On ni Oluwa Ọlọrun wa, idajọ rẹ̀ mbẹ ni gbogbo aiye.
15 Ẹ ma ṣe iranti majẹmu rẹ̀ titi lai, ọ̀rọ ti o ti pa li aṣẹ fun ẹgbẹrun iran;
16 Majẹmu ti o ba Abrahamu da, ati ibura rẹ̀ fun Isaaki;
17 A si tẹnumọ eyi li ofin fun Jakobu, ati fun Israeli ni majẹmu aiyeraiye:
18 Wipe, Iwọ li emi o fi ilẹ Kenaani fun, ipin ilẹ-ini nyin.
19 Nigbati ẹnyin wà ni kiun ni iye, ani diẹ kiun, ati atipo ninu rẹ̀.