26 Nitori pe gbogbo oriṣa awọn enia, ere ni nwọ́n: ṣugbọn Oluwa li o da awọn ọrun.
27 Ogo on ọlá wà niwaju rẹ̀; agbara ati ayọ̀ mbẹ ni ipò rẹ̀.
28 Ẹ fi fun Oluwa, ẹnyin ibatan enia, ẹ fi ogo ati ipa fun Oluwa.
29 Ẹ fi ogo fun Oluwa ti o yẹ fun orukọ rẹ̀: mu ọrẹ wá, ki ẹ si wá siwaju rẹ̀: ẹ sin Oluwa ninu ẹwà ìwa-mimọ́.
30 Ẹ warìri niwaju rẹ̀, gbogbo aiye aiye pẹlu si fi idi mulẹ ti kì o fi le yi.
31 Jẹ ki awọn ọrun ki o yọ̀, si jẹ ki inu aiye ki o dùn; si jẹ ki a wi ninu awọn orilẹ-ède pe, Oluwa jọba.
32 Jẹ ki okun ki o ma ho, ati ẹkún rẹ̀: jẹ ki papa-oko tùtu ki o yọ̀, ati ohun gbogbo ti mbẹ ninu rẹ̀.