34 Ẹ fi ọpẹ fun Oluwa, nitori ti o ṣeun: nitoriti ãnu rẹ̀ duro lailai.
35 Ki ẹ si wipe, Gbà wa Ọlọrun igbala wa, si gbá wa jọ, ki o si gbà wa lọwọ awọn keferi, ki awa ki o le ma fi ọpẹ fun orukọ rẹ mimọ́, ki a si le ma ṣogo ninu iyin rẹ.
36 Olubukún li Oluwa Ọlọrun Israeli lai ati lailai. Gbogbo awọn enia si wipe, Amin, nwọn si yìn Oluwa.
37 Bẹ̃ li o fi Asafu ati awọn arakunrin rẹ̀ silẹ nibẹ niwaju apoti ẹri majẹmu Oluwa lati ma jọsìn niwaju apoti ẹri na nigbagbogbo, bi iṣẹ ojojumọ ti nfẹ.
38 Ati Obed-Edomu pẹlu awọn arakunrin wọn, enia mejidilãdọrin; ati Obed-Edomu ọmọ Jedutuni, ati Hosa lati ma ṣe adena:
39 Sadoku alufa, ati awọn arakunrin rẹ̀, awọn alufa, niwaju agọ Oluwa, ni ibi giga ti o wà ni Gibeoni,
40 Lati ma ru ẹbọ sisun si Oluwa lori pẹpẹ ẹbọ sisun nigbagbogbo li owurọ ati li alẹ, gẹgẹ bi gbogbo eyi ti a kọ ninu ofin Oluwa, ti o pa li aṣẹ fun Israeli;