11 Yio si ṣe, nigbati ọjọ rẹ ba pe, ti iwọ o lọ pẹlu awọn baba rẹ, ni emi o gbé iru-ọmọ rẹ dide lẹhin rẹ, ti yio jẹ ọkan ninu awọn ọmọ rẹ ọkunrin; emi o si fi idi ijọba rẹ̀ mulẹ.
12 On o kọ́ ile fun mi, emi o si fi idi itẹ rẹ̀ mulẹ lailai.
13 Emi o jẹ baba fun u, on o si jẹ ọmọ fun mi; emi kì yio si gbà ãnu mi kuro lọdọ rẹ̀, bi mo ti gbà a lọwọ ẹniti o ti wà ṣaju rẹ:
14 Ṣugbọn emi o fi idi rẹ̀ kalẹ ninu ile mi ati ninu ijọba mi lailai, a o si fi idi itẹ rẹ̀ mulẹ lailai.
15 Gẹgẹ bi gbogbo ọ̀rọ wọnyi, ati gẹgẹ bi gbogbo iran yi, bẹ̃ni Natani sọ fun Dafidi.
16 Dafidi ọba si wá, o si joko niwaju Oluwa, o si wipe, Tali emi Oluwa Ọlọrun, ati kini ile mi, ti iwọ si mu mi de ihinyi?
17 Ohun kekere si li eyi li oju rẹ, Ọlọrun: iwọ si ti sọ pẹlu sipa ile iranṣẹ rẹ fun akokò jijin ti mbọ, o si ka mi si bi iṣe enia giga, Oluwa Ọlọrun.