20 Oluwa, kò si ẹniti o dabi rẹ bẹ̃ni kò si Ọlọrun miran lẹhin rẹ, gẹgẹ bi gbogbo eyi ti awa ti fi eti wa gbọ́.
21 Orilẹ-ède kan wo li o wà li aiye ti o dabi enia rẹ, Israeli, ti Ọlọrun lọ irapada lati ṣe enia on tikararẹ, lati ṣe orukọ fun ara rẹ nipa ohun ti o tobi ti o si lẹ̀ru, ni lile awọn orilẹ-ède jade kuro niwaju awọn enia rẹ, ti iwọ ti rapada lati Egipti jade wá?
22 Nitori awọn enia rẹ Israeli li o ti ṣe li enia rẹ titi lai; iwọ Oluwa, si di Ọlọrun wọn.
23 Njẹ nisisiyi, Oluwa! jẹ ki ọ̀rọ ti iwọ ti sọ niti iranṣẹ rẹ, ati niti ile rẹ̀ ki o fi idi mulẹ lailai, ki iwọ ki o si ṣe bi iwọ ti wi.
24 Ani, jẹ ki o fi idi mulẹ, ki a le ma gbé orukọ rẹ ga lailai, wipe, Oluwa awọn ọmọ ogun li Ọlọrun Israeli, ani Ọlọrun fun Israeli; si jẹ ki ile Dafidi iranṣẹ rẹ ki o fi idi mulẹ niwaju rẹ.
25 Nitori iwọ, Ọlọrun mi, ti ṣi iranṣẹ rẹ li eti pe, Iwọ o kọ́ ile kan fun u: nitorina ni iranṣẹ rẹ ri i lati gbadua niwaju rẹ.
26 Njẹ nisisiyi Oluwa, Iwọ li Ọlọrun, iwọ si ti sọ ọ̀rọ ore yi fun iranṣẹ rẹ;