6 Nibikibi ti mo ti nrin larin gbogbo Israeli, emi ha sọ̀rọ kan fun ọkan ninu awọn onidajọ Israeli, ti emi ti paṣẹ fun lati ma bọ awọn enia mi, emi ha ti wipe, Ẽṣe ti ẹnyin kò fi kọ́ ile igi kedari fun mi bi?
7 Njẹ nitorina bayi ni iwọ o wi fun Dafidi iranṣẹ mi, Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, Emi mu ọ kuro ni pápá oko-tutu, ani kuro lati ma tọ agutan lẹhin, ki iwọ ki o le ma ṣe olori awọn enia mi Israeli.
8 Emi si ti wà pẹlu rẹ ni ibikibi ti iwọ ba lọ, emi si ti ké gbogbo awọn ọta rẹ kuro niwaju rẹ, emi o si ṣe ọ li olorukọ kan, bi orukọ awọn enia nla ti o ti wà li aiye.
9 Emi o si yan ibi kan fun Israeli awọn enia mi, emi o si gbìn wọn, ki nwọn le má gbe ipò wọn, a kì yio si ṣì wọn mọ; bẹ̃ni ọmọ buburu kì yio yọ wọn lẹnu mọ, bi ti atijọ;
10 Ati bi igba ti emi ti fi enia jẹ onidajọ lori awọn enia mi Israeli. Ati pẹlu emi o ṣẹgun gbogbo awọn ọta rẹ. Pẹlupẹlu mo ti sọ fun ọ pe, Oluwa yio kọle kan fun ọ.
11 Yio si ṣe, nigbati ọjọ rẹ ba pe, ti iwọ o lọ pẹlu awọn baba rẹ, ni emi o gbé iru-ọmọ rẹ dide lẹhin rẹ, ti yio jẹ ọkan ninu awọn ọmọ rẹ ọkunrin; emi o si fi idi ijọba rẹ̀ mulẹ.
12 On o kọ́ ile fun mi, emi o si fi idi itẹ rẹ̀ mulẹ lailai.