1 O SI ṣe lẹhin eyi, ni Dafidi kọlu awọn ara Filistia, o si ṣẹ́ wọn, o si gbà Gati ati ilu rẹ̀ lọwọ awọn ara Filistia.
2 O si kọlu Moabu, awọn ara Moabu si di iranṣẹ Dafidi, nwọn si mu ọrẹ wá.
3 Dafidi si kọlu Hadareseri ọba Soba ni Hamati bi o ti nlọ lati fi idi ijọba rẹ̀ mulẹ leti odò Euferate.
4 Dafidi si gbà ẹgbẹrun kẹkẹ́, ati ẹ̃dẹgbarun ẹlẹṣin, ati ẹgbãwa ẹlẹsẹ lọwọ rẹ̀: Dafidi si ja iṣan ẹsẹ gbogbo awọn ẹṣin kẹkẹ́ na, ṣugbọn o pa ọgọrun ẹṣin kẹkẹ́ mọ ninu wọn.
5 Nigbati awọn ara Siria ti Damasku wá lati ran Hadareseri ọba Soba lọwọ, Dafidi pa ẹgbã mọkanla enia ninu awọn ara Siria.
6 Dafidi si fi ẹgbẹ-ogun si Siria ti Damasku; awọn ara Siria si di iranṣẹ Dafidi, nwọn si mu ọrẹ wá. Bayi li Oluwa gbà Dafidi nibikibi ti o ba nlọ.
7 Dafidi si gbà awọn asa wura ti mbẹ lara awọn iranṣẹ Hadareseri, o si mu wọn wá si Jerusalemu.