5 Nigbati awọn ara Siria ti Damasku wá lati ran Hadareseri ọba Soba lọwọ, Dafidi pa ẹgbã mọkanla enia ninu awọn ara Siria.
6 Dafidi si fi ẹgbẹ-ogun si Siria ti Damasku; awọn ara Siria si di iranṣẹ Dafidi, nwọn si mu ọrẹ wá. Bayi li Oluwa gbà Dafidi nibikibi ti o ba nlọ.
7 Dafidi si gbà awọn asa wura ti mbẹ lara awọn iranṣẹ Hadareseri, o si mu wọn wá si Jerusalemu.
8 Lati Tibhati pẹlu ati lati Kuni, ilu Hadareseri ni Dafidi ko ọ̀pọlọpọ idẹ, eyiti Solomoni fi ṣe okun idẹ, ọwọn wọnni, ati ohun elo idẹ wọnni.
9 Nigbati Tou ọba Hamati gbọ́ pe Dafidi ti pa gbogbo ogun Hadareseri ọba Soba.
10 O ran Hadoramu ọmọ rẹ̀ si Dafidi ọba lati ki i ati lati yọ̀ fun u, nitoriti o ti ba Hadareseri jà o si ti ṣẹgun rẹ̀; (nitori Tou ti jẹ ọta Hadareseri) o si ni oniruru ohun elo wura ati ti fadakà ati idẹ pẹ̀lu rẹ̀.
11 Awọn pẹlu ni Dafidi yà si mimọ́ fun Oluwa pẹlu fadakà ati wura ti o ko lati ọdọ gbogbo orilẹ-ède wọnni wá; lati Edomu, ati lati Moabu, ati lati ọdọ awọn ọmọ Ammoni, ati lati ọdọ awọn ara Filistia, ati lati Amaleki wá,