6 Nigbati awọn ọmọ Ammoni ri pe nwọn ti ba ara wọn jẹ lọdọ Dafidi, Hanuni ati awọn ọmọ Ammoni ran ẹgbẹrun talenti fadakà lati bẹ̀wẹ kẹkẹ́ ati ẹlẹsin lati Siria ni Mesopotamia wá, ati lati Siria-Maaka wá, ati lati Soba wá.
7 Bẹ̃ni nwọn bẹwẹ ẹgbã mẹrindilogun kẹkẹ́ ati ọba Maaka ati awọn enia rẹ̀; nwọn si wá nwọn si do niwaju Medeba. Awọn ọmọ Ammoni si ko ara wọn jọ lati ilu wọn, nwọn si wá si ogun.
8 Nigbati Dafidi gbọ́, o ran Joabu ati gbogbo ogun awọn akọni enia.
9 Awọn ọmọ Ammoni si jade wá, nwọn si tẹ ogun niwaju ẹnu-ibode ilu na: awọn ọba ti o wá si wà li ọtọ̀ ni igbẹ.
10 Nigbati Joabu ri pe a doju ija kọ on, niwaju ati lẹhin, o yàn ninu gbogbo ãyo Israeli, o si tẹ ogun wọn si awọn ara Siria.
11 O si fi iyokù awọn enia le Abiṣai arakunrin rẹ̀ lọwọ, nwọn si tẹ ogun si awọn ọmọ Ammoni.
12 On si wipe, Bi awọn ara Siria ba le jù fun mi, nigbana ni iwọ o ran mi lọwọ: ṣugbọn bi awọn ọmọ Ammoni ba le jù fun ọ, nigbana li emi o ràn ọ lọwọ.