30 Ati awọn ọmọ Nadabu; Seledi, ati Appaimu: ṣugbọn Seledi kú laini ọmọ.
31 Ati awọn ọmọ Appaimu; Iṣi. Ati awọn ọmọ Iṣi; Ṣeṣani. Ati awọn ọmọ Ṣeṣani. Ahlai.
32 Ati awọn ọmọ Jada arakunrin Ṣammai; Jeteri, ati Jonatani; Jeteri si kú laini ọmọ.
33 Awọn ọmọ Jonatani; Peleti, ati Sasa. Wọnyi ni awọn ọmọ Jerahmeeli.
34 Ṣeṣani kò si ni ọmọkunrin, bikọṣe ọmọbinrin. Ṣeṣani si ni iranṣẹ kan, ara Egipti, orukọ, ẹniti ijẹ Jarha.
35 Ṣeṣani si fi ọmọbinrin rẹ̀ fun Jarha iranṣẹ rẹ̀ li aya; on si bi Attai fun u.
36 Attai si bi Natani, Natani si bi Sabadi,