4 Tamari aya-ọmọ rẹ̀ si bi Faresi ati Sera fun u. Gbogbo awọn ọmọ Juda jẹ marun.
5 Awọn ọmọ Faresi; Hesroni; ati Hamuli.
6 Ati awọn ọmọ Sera; Simri, ati Etani, ati Hemani, ati Kalkoli, ati Dara: gbogbo wọn jẹ marun.
7 Ati awọn ọmọ Karmi; Akari, oniyọnu Israeli, ẹniti o dẹṣẹ niti ohun iyasọtọ̀.
8 Awọn ọmọ Etani; Asariah.
9 Awọn ọmọ Hesroni pẹlu ti a bi fun u; Jerahmeeli, ati Ramu, ati Kelubai.
10 Ramu si bi Amminadabu; Amminadabu si bi Naṣoni, ijoye awọn ọmọ Juda;