16 Dafidi si gbé oju rẹ̀ soke, o si ri angeli Oluwa na duro lagbedemeji aiye ati ọrun, o ni idà fifayọ lọwọ rẹ̀ ti o si nà sori Jerusalemu. Nigbana ni Dafidi ati awọn àgbagba Israeli, ti o wọ aṣọ ọ̀fọ, da oju wọn bolẹ.
17 Dafidi si wi fun Ọlọrun pe, Emi kọ́ ha paṣẹ lati kaye awọn enia? ani emi li ẹniti o ṣẹ̀ ti mo si ṣe buburu pãpã; ṣugbọn bi o ṣe ti agutan wọnyi, kini nwọn ṣe? Emi bẹ̀ ọ, Oluwa Ọlọrun mi, jẹ ki ọwọ rẹ ki o wà li ara mi, ati lara ile baba mi; ṣugbọn ki o máṣe li ara awọn enia rẹ ti a o fi arùn kọlu wọn.
18 Nigbana ni angeli Oluwa na paṣẹ fun Gadi lati sọ fun Dafidi pe, ki Dafidi ki o gòke lọ ki o si tẹ pẹpẹ kan fun Oluwa, ni ilẹ ipaka Ornani, ara Jebusi.
19 Dafidi si gòke lọ nipa ọ̀rọ Gadi, ti o sọ li orukọ Oluwa.
20 Ornani si yipada, o si ri angeli na; ati awọn ọmọ rẹ̀ mẹrin pẹlu rẹ̀ pa ara wọn mọ́. Njẹ Ornani npa ọka lọwọ.
21 Bi Dafidi si ti de ọdọ Ornani, Ornani si wò, o si ri Dafidi, o si ti ibi ilẹ ipaka rẹ̀ jade, o si wolẹ, o dojubolẹ fun Dafidi.
22 Dafidi si wi fun Ornani pe, Fun mi ni ibi ipaka yi, ki emi ki o le tẹ pẹpẹ kan nibẹ fun Oluwa; iwọ o si fi fun mi ni iye owo rẹ̀ pipe; ki a le da ajakalẹ arun duro lọdọ awọn enia.