7 Dafidi si wi fun Solomoni pe, Ọmọ mi, bi o ṣe ti emi ni, o ti wà li ọkàn mi lati kọ́le kan fun orukọ Oluwa Ọlọrun mi:
8 Ṣugbọn ọ̀rọ Oluwa tọ̀ mi wá, wipe, Iwọ ti ta ẹ̀jẹ silẹ li ọ̀pọlọpọ, iwọ si ti ja ogun nlanla: iwọ kò gbọdọ kọ́ ile fun orukọ mi, nitoriti iwọ ta ẹ̀jẹ pipọ̀ silẹ niwaju mi.
9 Kiyesi i, a o bi ọmọ kan fun ọ, ẹniti yio ṣe enia isimi; emi o si fun u ni isimi lọdọ gbogbo awọn ọta rẹ̀ yika kiri: nitori orukọ rẹ̀ yio ma jẹ Solomoni, emi o si fi alafia ati idakẹjẹ fun Israeli li ọjọ aiye rẹ̀.
10 On o kọ ile kan fun orukọ mi; on o si jẹ ọmọ mi; emi o si jẹ baba fun u; emi o si fi idi itẹ ijọba rẹ̀ mulẹ lori Israeli lailai.
11 Njẹ ọmọ mi, ki Oluwa ki o pẹlu rẹ; iwọ si ma pọ̀ si i, ki o si kọ́ ile Oluwa Ọlọrun rẹ, bi o ti sọ nipa tirẹ.
12 Kiki ki Oluwa ki o fun ọ li ọgbọ́n ati oye, ki o si fun ọ li aṣẹ niti Israeli, ki iwọ ki o le pa ofin Oluwa Ọlọrun rẹ mọ́.
13 Nigbana ni iwọ o ma pọ̀ si i, bi iwọ ba ṣe akiyesi lati mu aṣẹ ati idajọ ti Oluwa pa fun Mose ṣẹ niti Israeli: mura giri ki o si ṣe onigboya, má bẹ̀ru bẹ̃ni ki aiya ki o máṣe fò ọ.