22 Eleasari kú, kò si li ọmọkunrin bikòṣe ọmọbinrin: awọn arakunrin wọn awọn ọmọ Kiṣi si fẹ wọn li aiya.
23 Awọn ọmọ Muṣi; Mali, ati Ederi, ati Jeremoti, mẹta.
24 Wọnyi ni awọn ọmọ Lefi, bi ile baba wọn; ani olori awọn baba, bi a ti ka wọn ni iye orukọ, nipa ori wọn, awọn ti o ṣiṣẹ ìsin ile Oluwa, lati iwọn ogun ọdun ati jù bẹ̃ lọ.
25 Nitori Dafidi wipe, Oluwa Ọlọrun Israeli ti fi isimi fun awọn enia rẹ̀, on si ngbé Jerusalemu lailai:
26 Ati pẹlu awọn ọmọ Lefi: nwọn kì yio si tun rù ibugbe na mọ, ati gbogbo ohun elo rẹ̀ fun ìsin rẹ̀.
27 Nitori nipa ọ̀rọ ikẹhin Dafidi, ni kika iye awọn ọmọ Lefi lati ìwọn ogun ọdun ati jù bẹ̃ lọ:
28 Nitori iṣẹ wọn ni lati duro tì awọn ọmọ Aaroni, fun ìsin ile Oluwa, niti àgbala, ati niti iyẹwu, ati niti ṣiṣe ohun èlo wọnni ni mimọ́, ati iṣẹ ìsin ile Ọlọrun;