1 NJẸ awọn ọmọ Israeli nipa iye wọn, eyini ni, awọn olori baba, ati awọn balogun ẹgbẹgbẹrun, ati ọrọrun, ati awọn ijoye wọn ti nsìn ọba ni olukuluku ọ̀na li ẹgbẹgbẹ, ti nwọle ti si njade li oṣoṣù ni gbogbo oṣù ọdun, jẹ́ ẹgbã mejila.
2 Lori ẹgbẹ kini ti oṣù kini ni Jaṣobeamu ọmọ Sabdieli: ẹgbã mejila li o si wà ninu ẹgbẹ tirẹ̀.
3 Ninu awọn ọmọ Peresi on ni olori fun gbogbo awọn olori ogun ti oṣù ekini.
4 Ati lori ẹgbẹ ti oṣù keji ni Dodai ara Ahohi, ati ẹgbẹ tirẹ̀; Mikloti pẹlu nṣe balogun: ẹgbã mejila li o wà ninu ẹgbẹ tirẹ̀ pẹlu.
5 Olori ogun kẹta fun oṣù kẹta ni Benaiah ọmọ Jehoiada alufa, olori kan: ẹgbã mejila li o si wà ninu ẹgbẹ tirẹ̀.
6 Eyini ni Benaiah na, akọni enia, ninu awọn ọgbọ̀n, o si jẹ olori awọn ọgbọ̀n: Amisabadi ọmọ rẹ̀ si wà ninu ẹgbẹ tirẹ̀.
7 Olori ogun kẹrin fun oṣù kẹrin ni Asaheli arakunrin Joabu, ati Sebadiah ọmọ rẹ̀ lẹhin rẹ̀: ẹgbã mejila li o si wà ninu ẹgbẹ tirẹ̀.