2 Nigbana ni Dafidi ọba dide duro li ẹsẹ rẹ̀, o si wipe, Ẹ gbọ́ ti emi, ẹnyin arakunrin mi ati enia mi: emi fẹ li ọkàn mi lati kọ́ ile isimi kan fun apoti ẹri majẹmu Oluwa, ati fun itisẹ Ọlọrun wa, mo si ti mura tan fun kikọ́le na:
3 Ṣugbọn Ọlọrun sọ fun mi pe, Iwọ kò gbọdọ kọ́ ile fun orukọ mi, nitori ologun ni iwọ, o si ti ta ẹ̀jẹ silẹ.
4 Oluwa Ọlọrun Israeli si yàn mi lati inu gbogbo ile baba mi lati jẹ ọba lori Israeli lailai: nitori ti o ti yàn Juda li olori; ati ninu ile Juda, ile baba mi: ati larin awọn ọmọ baba mi o fẹ mi lati jẹ ọba gbogbo Israeli.
5 Ati ninu gbogbo ọmọ mi ọkunrin (nitori ti Oluwa ti fun mi li ọmọkunrin pupọ), o ti yàn Solomoni ọmọ mi lati joko lori itẹ ijọba Oluwa lori Israeli.
6 On si wi fun mi pe, Solomoni ọmọ rẹ, on yio kọ́ ile mi ati agbala mi: nitori emi ti yàn a li ọmọ mi, emi o si jẹ baba fun u.
7 Pẹlupẹlu emi o fi idi ijọba rẹ̀ mulẹ lailai, bi o ba murale lati ṣe ofin mi ati idajọ mi bi li oni yi.
8 Njẹ nisisiyi li oju gbogbo Israeli ijọ enia Oluwa, ati li eti Ọlọrun wa, ẹ ma pamọ́ ki ẹ si ma ṣafẹri gbogbo ofin Oluwa Ọlọrun nyin: ki ẹ le ni ilẹ rere yi, ki ẹ si le fi i silẹ li ogún fun awọn ọmọ nyin lẹhin nyin lailai.