4 Awọn mẹfa wọnyi li a bi fun u ni Hebroni; nibẹ li o si jọba li ọdun meje on oṣù mẹfa: ati ni Jerusalemu li o jọba li ọdun mẹtalelọgbọn.
5 Wọnyi li a si bi fun u ni Jerusalemu; Ṣimea, ati Ṣobabu, ati Natani, ati Solomoni, mẹrin, lati ọdọ Batṣua ọmọbinrin Ammieli:
6 Abhari pẹlu, ati Eliṣama, ati Elifeleti,
7 Ati Noga, ati Nefegi, ati Jafia,
8 Ati Eliṣama, ati Eliada, ati Elifeleti mẹsan.
9 Wọnyi ni gbogbo awọn ọmọ Dafidi, laika awọn ọmọ àle rẹ̀, ati Tamari arabinrin wọn.
10 Ọmọ Solomoni si ni Rehoboamu, Abia ọmọ rẹ̀, Asa ọmọ rẹ̀, Jehoṣafati ọmọ rẹ̀.