3 Awọn wọnyi li o ti ọdọ baba Etamu wá; Jesreeli ati Jisma, ati Jidbaṣi: orukọ arabinrin wọn si ni Selelponi:
4 Ati Penueli ni baba Gedori, ati Eseri baba Huṣa. Wọnyi ni awọn ọmọ Huri, akọbi Efrata, baba Betlehemu.
5 Aṣuri baba Tekoa si li aya meji, Hela ati Naara.
6 Naara si bi Ahusamu, ati Heferi, ati Temeni, ati Ahaṣtari fun u. Wọnyi li awọn ọmọ Naara.
7 Ati awọn ọmọ Hela ni Sereti, ati Jesoari, ati Etnani.
8 Kosi si bi Anubu, ati Sobeba, ati awọn idile Aharheli, ọmọ Harumu.
9 Jabesi si ṣe ọlọla jù awọn arakunrin rẹ̀ lọ: iya rẹ̀ si pe orukọ rẹ̀ ni Jabesi, wipe, Nitoriti mo bi i pẹlu ibanujẹ.