9 Jabesi si ṣe ọlọla jù awọn arakunrin rẹ̀ lọ: iya rẹ̀ si pe orukọ rẹ̀ ni Jabesi, wipe, Nitoriti mo bi i pẹlu ibanujẹ.
10 Jabesi si ké pè Ọlọrun Israeli, wipe, Iwọ iba jẹ bukún mi nitõtọ, ki o si sọ àgbegbe mi di nla, ki ọwọ rẹ ki o si wà pẹlu mi, ati ki iwọ ki o má si jẹ ki emi ri ibi, ki emi má si ri ibinujẹ! Ọlọrun si mu ohun ti o tọrọ ṣẹ.
11 Kelubu arakunrin Ṣua si bi Mehiri, ti iṣe baba Eṣtoni.
12 Eṣtoni si bi Bet-rafa, ati Pasea, ati Tehinna baba ilu Nahaṣi. Wọnyi li awọn ọkunrin Reka,
13 Ati awọn ọmọ Kenasi; Otnieli, ati Seraiah: ati awọn ọmọ Otnieli; Hatati.
14 Meonotai si bi Ofra: Seraiah si bi Joabu, baba Geharasimu; nitori oniṣọnà ni nwọn.
15 Ati awọn ọmọ Kalebu ọmọ Jefunne; Iru, Ela, ati Naamu: ati awọn ọmọ Ela, ani Kenasi.