14 Asariah si bi Seraiah, Seraiah si bi Jehosadaki,
15 Jehosadaki si lọ si oko ẹrú, nigbati Oluwa kó Juda ati Jerusalemu lọ nipa ọwọ Nebukadnessari.
16 Awọn ọmọ Lefi; Gersọmu, Kohati, ati Merari.
17 Wọnyi si li orukọ awọn ọmọ Gerṣomu, Libni, ati Ṣimei.
18 Awọn ọmọ Kohati ni, Amramu, ati Ishari, ati Hebroni, ati Ussieli.
19 Awọn ọmọ Merari; Mahli ati Muṣi. Wọnyi si ni idile awọn ọmọ Lefi, gẹgẹ bi awọn baba wọn.
20 Ti Gerṣomu; Libni ọmọ rẹ̀, Jahati ọmọ rẹ̀, Simma ọmọ rẹ̀.