33 Wọnyi si li awọn ti o duro pẹlu awọn ọmọ wọn. Ninu awọn ọmọ Kohati: Hemani akọrin, ọmọ Joeli, ọmọ Samueli,
34 Ọmọ Elkana, ọmọ Jerohamu, ọmọ Elieli, ọmọ Toha,
35 Ọmọ Sufu, ọmọ Elkana, ọmọ Mahati, ọmọ Amasai,
36 Ọmọ Elkana, ọmọ Joeli, ọmọ Asariah, ọmọ Sefaniah,
37 Ọmọ Tahati, ọmọ Assiri, ọmọ Ebiasafu, ọmọ Kora,
38 Ọmọ Ishari, ọmọ Kohati, ọmọ Lefi, ọmọ Israeli.
39 Ati arakunrin rẹ̀ Asafu, ti o duro li ọwọ ọ̀tun rẹ̀, ani Asafu, ọmọ Berakiah, ọmọ Ṣimea,