45 Ọmọ Haṣabiah, ọmọ Amasiah, ọmọ Hilkiah,
46 Ọmọ Amsi, ọmọ Bani, ọmọ Ṣameri.
47 Ọmọ Mahli, ọmọ Muṣi ọmọ Merari, ọmọ Lefi,
48 Arakunrin wọn pẹlu, awọn ọmọ Lefi, li a yàn si oniruru iṣẹ gbogbo ti agọ ile Ọlọrun.
49 Ṣugbọn Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ nrubọ lori pẹpẹ ẹbọ sisun, ati lori pẹpẹ turari, a si yàn wọn si gbogbo iṣẹ ibi mimọ́-jùlọ, ati lati ṣe ètutu fun Israeli, gẹgẹ bi gbogbo eyi ti Mose, iranṣẹ Ọlọrun, ti pa li aṣẹ.
50 Wọnyi si li awọn ọmọ Aaroni; Eleasari ọmọ rẹ̀, Finehasi ọmọ rẹ̀, Abiṣua ọmọ rẹ̀,
51 Bukki ọmọ rẹ̀, Ussi ọmọ rẹ̀, Serahiah ọmọ rẹ̀,