50 Wọnyi si li awọn ọmọ Aaroni; Eleasari ọmọ rẹ̀, Finehasi ọmọ rẹ̀, Abiṣua ọmọ rẹ̀,
51 Bukki ọmọ rẹ̀, Ussi ọmọ rẹ̀, Serahiah ọmọ rẹ̀,
52 Meraioti ọmọ rẹ̀, Amariah ọmọ rẹ̀, Ahitubu ọmọ rẹ̀,
53 Sadoku ọmọ rẹ̀, Ahimaasi ọmọ rẹ̀.
54 Wọnyi si ni ibùgbe wọn gẹgẹ bi budo wọn li àgbegbe wọn, ti awọn ọmọ Aaroni, ti idile awọn ọmọ Kohati: nitori ti wọn ni ipin ikini.
55 Nwọn si fun wọn ni Hebroni ni ilẹ Juda, ati ìgberiko rẹ̀ yi i kakiri.
56 Ṣugbọn oko ilu na, ati ileto wọn, ni nwọn fun Kalebu ọmọ Jefunne.