69 Ati Aijaloni pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Gatrimmoni pẹlu ìgberiko rẹ̀:
70 Ati lati inu àbọ ẹ̀ya Manasse; Aneri pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Bileamu pẹlu ìgberiko rẹ̀, fun idile awọn ọmọ Kohati iyokù.
71 Awọn ọmọ Gerṣomu lati inu idile àbọ ẹ̀ya Manasse li a fi Golani ni Baṣani fun pẹlu ìgberiko rẹ̀; ati Aṣtaroti pẹlu ìgberiko rẹ̀,
72 Ati lati inu ẹ̀ya Issakari; Kadeṣi pẹlu ìgberiko rẹ̀; Daberati pẹlu ìgberiko rẹ̀,
73 Ati Ramoti pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Anemu pẹlu ìgberiko rẹ̀:
74 Ati lati inu ẹ̀ya Aṣeri; Maṣali pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Abdoni pẹlu ìgberiko rẹ̀.
75 Ati Hakoku pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Rehobu pẹlu ìgberiko rẹ̀: