72 Ati lati inu ẹ̀ya Issakari; Kadeṣi pẹlu ìgberiko rẹ̀; Daberati pẹlu ìgberiko rẹ̀,
73 Ati Ramoti pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Anemu pẹlu ìgberiko rẹ̀:
74 Ati lati inu ẹ̀ya Aṣeri; Maṣali pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Abdoni pẹlu ìgberiko rẹ̀.
75 Ati Hakoku pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Rehobu pẹlu ìgberiko rẹ̀:
76 Ati lati inu ẹ̀ya Naftali; Kedeṣi ni Galili pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Hammoni pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Kirjataimu pẹlu ìgberiko rẹ̀.
77 Fun iyokù awọn ọmọ Merari li a fi Rimmoni pẹlu ìgberiko rẹ̀ fun, Tabori pẹlu ìgberiko rẹ̀, lati inu ẹ̀ya Sebuluni:
78 Ati li apa keji Jordani leti Jeriko, ni iha ariwa Jordani, li a fi Beseri li aginju pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Jasa pẹlu ìgberiko rẹ̀ fun wọn, lati inu ẹ̀ya Rubeni,