78 Ati li apa keji Jordani leti Jeriko, ni iha ariwa Jordani, li a fi Beseri li aginju pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Jasa pẹlu ìgberiko rẹ̀ fun wọn, lati inu ẹ̀ya Rubeni,
79 Ati Kedemoti pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Mefaati pẹlu ìgberiko rẹ̀:
80 Ati lati inu ẹ̀ya Gadi, Ramoti ni Gileadi pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Mahanaimu pẹlu ìgberiko rẹ̀.
81 Ati Heṣboni pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Jaseri pẹlu ìgberiko rẹ̀.