1 AWỌN ọmọ Issakari si ni, Tola, ati Pua, Jaṣubu, ati Ṣimroni, mẹrin.
2 Ati awọn ọmọ Tola; Ussi, ati Refaiah, ati Jerieli, ati Jamai, ati Jibsamu ati Samueli, awọn olori ile baba wọn, eyini ni ti Tola: akọni alagbara enia ni wọn ni iran wọn; iye awọn ẹniti o jẹ ẹgbã mọkanla o le ẹgbẹta li ọjọ Dafidi.
3 Awọn ọmọ Ussi: Israhiah ati awọn ọmọ Israhiah; Mikaeli, ati Obadiah, ati Joeli, ati Iṣiah, marun: gbogbo wọn li olori.
4 Ati pẹlu wọn, nipa iran wọn, gẹgẹ bi ile baba wọn, ni awọn ẹgbẹ ọmọ-ogun fun ogun, ẹgbã mejidilogun enia: nitoriti nwọn ni ọ̀pọlọpọ obinrin ati ọmọ ọkunrin.
5 Ati awọn arakunrin wọn ninu gbogbo idile Issakari jẹ akọni alagbara enia, ni kikaye gbogbo wọn nipa iran wọn, nwọn jẹ ẹgbamẹtalelogoji o le ẹgbẹrun.
6 Awọn ọmọ Benjamini: Bela, ati Bekeri, ati Jediaeli, mẹta.
7 Awọn ọmọ Bela; Esboni, ati Ussi, ati Ussieli ati Jerimoti ati Iri, marun; awọn olori ile baba wọn, akọni alagbara enia; a si kaye wọn nipa iran wọn si ẹgbãmọkanla enia o le mẹrinlelọgbọ̀n.