7 Ati Naamani, ati Ahiah, ati Gera, o si ko wọn kuro, o si bi Ussa ati Ahihudi.
8 Ṣaharaimu si bi ọmọ ni ilẹ Moabu; lẹhin igbati o ti ran wọn lọ tan; Huṣimu ati Baera si li awọn aya rẹ̀.
9 Hodeṣi, aya rẹ̀ si bi, Jobabu, ati Sibia, ati Meṣa, ati Malkama fun u,
10 Ati Jeusi, ati Ṣokia, ati Mirma. Wọnyi li awọn ọmọ rẹ̀, olori awọn baba.
11 Huṣimu si bi Ahitubu ati Elpaali fun u.
12 Awọn ọmọ Elpaali, Eberi, ati Miṣamu ati Ṣameri, ẹniti o kọ́ Ono ati Lodi pẹlu ilu wọn:
13 Beria pẹlu, ati Ṣema, ti nwọn iṣe olori awọn baba awọn ara Ajaloni, awọn ti o le awọn ara Gati kuro.