21 Sekariah ọmọ Meṣelemiah ni adena ilẹkun agọ ajọ enia.
22 Gbogbo wọnyi ti a ti yàn lati ṣe adena loju iloro, jẹ igba o le mejila. A ka awọn wọnyi nipa idile wọn ni ileto wọn, awọn ẹniti Dafidi ati Samueli, ariran, ti yàn nitori otitọ wọn.
23 Bẹ̃li awọn wọnyi ati awọn ọmọ wọn nṣẹ abojuto iloro ile Oluwa, eyini ni ile agọ na fun iṣọ.
24 Ni igun mẹrẹrin ni awọn adena mbẹ, niha ilà-õrùn, ìwọ-õrún, ariwa ati gusu.
25 Ati awọn arakunrin wọn ngbe ileto wọn, lati ma wá pẹlu wọn ni ijọ ekeje lati igba de igba.
26 Nitoriti awọn ọmọ Lefi wọnyi jẹ awọn olori adena mẹrin, nwọn si wà ninu iṣẹ na, nwọn si wà lori iyara ati ibi iṣura ile Ọlọrun.
27 Nwọn a si ma sùn yi ile Ọlọrun ka, nitori ti nwọn ni itọju na, ati ṣiṣi rẹ̀ li orowurọ jẹ ti wọn.