9 Amasiah si wi fun enia Ọlọrun na pe, Ṣugbọn kili awa o ha ṣe nitori ọgọrun talenti ti mo ti fi fun ẹgbẹ-ogun Israeli? Enia Ọlọrun na si dahùn pe, O wà li ọwọ Oluwa lati fun ọ li ọ̀pọlọpọ jù eyi lọ.
10 Nigbana li Amasiah yà wọn, ani ẹgbẹ-ogun ti o ti tọ̀ ọ lati Efraimu wá, lati tun pada lọ ile wọn: ibinu wọn si ru gidigidi si Juda, nwọn si pada si ile wọn ni irunu.
11 Amasiah si mu ara le, o si kó awọn enia rẹ̀ jade, o si lọ si afonifoji iyọ̀, o si pa ẹgbarun ninu awọn ọmọ Seiri.
12 Ati ẹgbãrun alãye li awọn ọmọ Juda kó ni igbekun lọ, nwọn si mu wọn lọ si òke apata na, nwọn si tãri wọn silẹ lati òke apata na, nwọn si fọ́ tũtu.
13 Ṣugbọn awọn ọmọ-ogun ti Amasiah ran pada lọ, ki nwọn ki o máṣe ba on lọ si ogun, kọlù awọn ilu Juda lati Samaria titi de Bet-horoni, nwọn si pa ẹgbẹdogun ninu wọn, nwọn si kó ikógun pipọ.
14 O si ṣe lẹhin ti Amasiah ti ibi pipa awọn ara Edomu bọ̀, o si mu awọn oriṣa awọn ọmọ Seiri bọ̀, o si gà wọn li oriṣa fun ara rẹ̀, o si tẹ̀ ara rẹ̀ ba niwaju wọn, o si sun turari fun wọn.
15 Nitorina ni ibinu Oluwa ru si Amasiah, o si ran woli kan si i, ti o wi fun u pe, Ẽṣe ti iwọ fi nwá oriṣa awọn enia na, ti kò le gbà awọn enia wọn lọwọ rẹ?