1 Sámúẹ́lì 29:1-7 BMY

1 Àwọn Fílístínì sì kó gbogbo ogun wọn jọ sí Áfékì: Ísírẹ́lì sì dó ni ibi ìsun omi tí ó wà ní Jésírélì.

2 Àwọn ìjòyé Fílístínì sì kọjá ní ọ̀rọ̀ọ̀rún àti lẹ́gbẹgbẹ̀rún; Dáfídì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ pẹ̀lú Ákíṣì sì kẹ́yìn.

3 Àwọn ìjòyé Fílístínì sì béèrè wí pé, “Kín ni àwọn Hébérù ń ṣe nìhìn-ín yìí?”Ákíṣì sì wí fún àwọn ìjòyè Fílístínì pé “Dáfídì kọ yìí, ìránṣẹ́ Ṣọ́ọ̀lù ọba Ísírẹ́lì, tí ó wà lọ́dọ̀ mi láti ọjọ́ wọ̀nyí tàbí láti ọdún wọ̀nyí, èmi kò ì tì í rí àṣìṣe kan ni ọwọ́ rẹ̀ lati ọjọ́ tí ó ti dé ọ̀dọ̀ mi títí di òní yìí.”

4 Àwọn ìjòyé Fílístínì sì bínú sí i; àwọn ìjòyé Fílístínì sì wí fún un pé, “Jẹ́ kí ọkùnrin yìí padà kí ó sì lọ sí ipó rẹ̀ tí ó fi fún un, kí ó má sì jẹ́ kí ó bá wa sọ̀kalẹ̀ lọ sí ogun, kí ó má ba à jásí ọ̀ta fún wa ni ogun; Kín ni òun ó fi ba olúwa rẹ̀ làjà, orí àwọn ènìyàn wọ̀nyí kọ́?

5 Ṣé èyí ni Dáfídì ti wọn torí rẹ̀ gberin ara wọn nínú ìjọ wí pé,“ ‘Ṣọ́ọ̀lù pa ẹgbẹgbẹrun rẹ̀,Dáfídì si pa ẹgbẹgbàárun tirẹ́.’ ”

6 Ákíṣì sì pe Dáfídì, ó sì wí fún un pé, “Bí Olúwa ti ń bẹ láàyè, ìwọ jẹ́ ólóòótọ́ àti ẹni ìwà rere lójú mi, ní àlọ rẹ àti ààbọ̀ rẹ pẹ̀lú mi ní ogun: nítorí pé èmi ko tìí ri búburú kan lọ́wọ́ rẹ́ láti ọjọ́ ti ìwọ ti tọ̀ mí wá, títí o fi dì òní yìí ṣùgbọ́n lójú àwọn ìjòyè, ìwọ kò ṣe ẹni tí ó tọ́.

7 Ǹjẹ́ yípadà kí o sì máa lọ ní àlàáfíà, kí ìwọ má ṣe bà àwọn Fílístínì nínú jẹ́.”