10 Ìwọ kò ha ti tún mí dà jáde bí i wàrà,ìwọ kò sì múmí dípò bí i wàràǹkàsì?
11 Ìwọ sá ti fi àwọ̀ ẹran ara wọ̀ mí,ìwọ sì fi egungun àti iṣan ṣọgbà yí mi ká.
12 Ìwọ ti fún mi ní ẹ̀mí àti ojú rere,ìbẹ̀wò rẹ sì pa ọkàn mi mọ́.
13 “Nǹkan wọ̀nyí ni ìwọ sì ti fi pamọ́ nínú rẹ;èmi mọ̀ pé, èyí ń bẹ ní ọkàn rẹ.
14 Bí mo bá ṣẹ̀, nígbà náà ni ìwọ yóò máa ṣọ́miìwọ kì yóò sì dárí àìṣedédé mi jìn.
15 Bí mo bá ṣe ẹni búburú, ègbé ni fún mi!Bí mo bá sì ṣe ẹni rere,bẹ́ẹ̀ ni èmi kò sì le gbe orí mi sókè.Nítorí mo wà nínú ìtọ́jú púpọ̀, mo sì wo ìpọ́jú mi.
16 Bí mo bá gbé orí mi ga. Ìwọ ń dẹ mí kiri bi i kìnnìhún;àti pẹ̀lú, ìwọ a sì fi ara rẹ hàn fún mi ní ìyànjú.