Jóòbù 26 BMY

Ìdáhùn Jóòbù

1 Ṣùgbọ́n Jóòbù sì dáhùn wí pé:

2 Báwo ni ìwọ ń ṣe ìrànlọ́wọ́ ẹni tíkò ní ipá, báwo ní ìwọ ń ṣe gbà apá ẹni tí kò ní agbára?

3 Báwo ni ìwọ ń ṣe ìgbìmọ̀ ẹni tí kòní ọgbọ́n, tàbí báwo ní ìwọ sọdi ọ̀ràn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ bí ó ti rí?

4 Ta ni ó ràn ọ́ lọ́wọ́ láti sọ àwọnọ̀rọ̀ wọ̀nyí, àti ẹ̀mi ta ni ó gba ẹnu rẹ sọ̀rọ̀?

5 “Àwọn aláìlágbára ti iṣà òkúwárìrì, lábẹ́ omi pẹ̀lú àwọn tí ń gbé inú rẹ̀.

6 Ìhòòhò ni ipò òkú níwájú Ọlọ́run,ibi ìparun kò sí ní ibojì.

7 Òun ní o nà ìhà àríwá ọ̀run ní ibiòfùrufú, ó sì fi ayé rọ̀ ní ojú òfo.

8 Ó di omi pọ̀ nínú ìkùùkù àwọsánmọ̀rẹ̀ tí ó nípọn; àwọsánmọ̀ kò sì ya nísàlẹ̀ wọn.

9 Ó sì fa ojú ìtẹ́ rẹ̀ sẹ́yìn, ó sì tẹàwọsánmọ̀ rẹ̀ sí i lórí.

10 Ó fi idẹ yí omi òkun ká, títí déààlà ìmọ́lẹ̀ àti òkùnkùn.

11 Ọ̀wọ̀n òpó ọ̀run wárìrì, ẹnu sì yàwọ́n sì ìbàwí rẹ̀.

12 Ó fi ipá rẹ̀ dààmú omi òkun; nípaòye rẹ̀, ó gé Ráhábù sí wẹ́ẹ́wẹ́.

13 Nípa ẹ̀mí rẹ̀ ni ó ti ṣe ọ̀run níọ̀sọ́; ọwọ́ rẹ̀ ni ó ti dá ejò wíwo nì.

14 Kíyèsí i, èyí ní òpin ọ̀nà rẹ̀;ohùn èyí tí a gbọ́ ti kéré tó!Ta ni ẹni náà tí òye àrá agbára rẹ̀ lè yé?”