1 Ígbà náà ni Élífásì, ará Témà dáhùn wí pé:
2 “Bí àwa bá fi ẹnu lé e, láti bá ọ sọ̀rọ̀, ìwọ o ha banújẹ́?Ṣùgbọ́n ta ni ó lè pa ọ̀rọ̀ mọ́ ẹnu láìsọ?
3 Kíyèsí i, ìwọ sá ti kọ́ ọ̀pọ̀ ènìyàn,ìwọ ṣá ti mú ọwọ́ aláìlera le.
4 Ọ̀rọ̀ rẹ ti gbé àwọn tí ń ṣubú lọ dúró,ìwọ sì ti mú eékún àwọn tí ń wárìrì lera.
5 Ṣùgbọ́n nísinsìnyí ó dé bá ọ, ó sì rẹ̀ ọ́, ó kọ lù ọ́;ara rẹ kò lélẹ̀.
6 Ìbẹ̀rù Ọlọ́run rẹ kò ha jẹ́ ìgbẹ́kẹ̀lé rẹàti ìdúró ọ̀nà rẹ kò ha sì jẹ́ ìrètí rẹ?
7 “Èmi bẹ̀ ọ́ rántí: Ta ni ó ṣègbé rí láìṣẹ̀?Tàbí níbo ni a gbé gé olódodo kúrò rí?
8 Àní bí èmi ti rí i pé, àwọn tí ń se ìtùlẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀,tí wọ́n sì fún irúgbìn ìwà búburú, wọn a sì ká èso rẹ̀ náà.
9 Nípa ìfẹ́ sí Ọlọ́run wọn a ṣègbé,nípa èémí ìbínú rẹ̀ wọn a parun.
10 Bíbú ramúramù kìnnìún àti ohùn òǹrorò kìnníunàti eyín àwọn ẹ̀gbọ̀rọ̀ kìnnìún ní a ká.
11 Ógbó kìnnìún kígbe, nítorí àìrí ohun ọdẹ,àwọn ẹ̀gbọrọ kìnnún sísanra ni a túká kiri.
12 “Ǹjẹ́ nísinsìn yìí a fí ohun lílùmọ́ kan hàn fún mi,etí mi sì gbà díẹ̀ nínú rẹ̀.
13 Ní ìrò ínú lojú ìrán òru,nígbà tí oorun èjìkà kùn ènìyàn.
14 Ẹ̀rù bà mí àti ìwárìrìtí ó mú gbogbo egungun mi jí pépé.
15 Nígbà náà ni iwin kan kọjá lọ ní iwájú mi,irun ara mi dìde ró ṣánṣán.
16 Ó dúró jẹ́ẹ́,ṣùgbọ́n èmi kò le wo àpẹẹrẹ ìrí rẹ̀,àwòrán kan hàn níwájú mi,ìdákẹ́ rọ́rọ́ wà, mo sì gbóhùn kan wí pé:
17 ‘Ẹni kíkú le jẹ́ olódodo níwájú Ọlọ́run,ènìyàn kò ha le mọ̀ ju Ẹlẹ́dàá rẹ̀ bí?
18 Kíyèsí i, òun kò gbẹ́kẹ̀lé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀,nínú àwọn ańgẹ́lì rẹ̀ ní ó sì rí ẹ̀ṣẹ̀
19 Áńbọ̀ńtórí àwọn tí ń gbé inú ilé amọ̀,ẹni tí ìbílẹ̀ wọ́n jẹ́ sí erùpẹ̀tí yóò di rírun kòkòrò.
20 A pa wọ́n run láti òwúrọ̀di alẹ́, wọ́n gbé láé láìrí ẹni kà á sí.
21 A kò ha ké okùn ìye wọ̀n kúrò bí?Wọ́n kú, àní láìlọ́gbọ́n?’