Jóòbù 35 BMY

Olótìítọ́ Ni Ọlọ́run

1 Elíhù sì wí pe:

2 “Ìwọ rò pé èyí ha tọ́, tí ìwọ wí pé,òdodo mi ni èyí níwájú Ọlọ́run?

3 Nítorí tí ìwọ wí pé èrè kí ní yóòjá sí fún ọ, tàbí èrè kí ni èmi yóò fi jẹ́ ju èrè ẹ̀ṣẹ̀ mi lọ.

4 “Èmi ó dá ọ lóhùn àti àwọn ẹgbẹ́ rẹpẹ̀lú rẹ.

5 Ṣíjú wo ọ̀run; kí o rí i, ki o sìbojúwo àwọ̀sánmọ̀ tí ó ga jù ọ lọ

6 Bí ìwọ bá sẹ̀ kí ni ìwọ fi sẹ̀ sí? Tàbíbí àìṣedéédéé rẹ di púpọ̀, kí ni ìwọ fi èyí nì ṣe sí i?

7 Bí ìwọ bá sì ṣe olódodo, kí ni ìwọfí fún u, tàbí kí ni òun rí gbà láti ọwọ́ rẹ wá?

8 Ìwà búburú rẹ ni fún ènìyàn bíìwọ; òdodo rẹ sì ni fún ọmọ ènìyàn.

9 “Nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìninilára, wọ́n múni kígbe; wọ́n kigbe nípa apá àwọn alágbára.

10 Ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó wí pé, ‘Níboni Ọlọ́run Ẹlẹ́dàá mi wà tí ó sì fi orin fún mi ní òru;

11 Tí òun kọ́ wa ní ẹ̀kọ́ jù àwọnẹranko ayé lọ, tí ó sì mú wagbọ́n ju àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run lọ?’

12 Nígbà náà ni wọ́n ń ké ṣùgbọ́nỌlọ́run kò dáhùn nítorí ìgbéraga ènìyàn búburú.

13 Nítòótọ́ Ọlọ́run kì yóò gbọ́ asán;bẹ́ẹ̀ ní Olódùmarè kì yóò kà á sí.

14 Bí ó tilẹ̀ ṣe pé ìwọ wí pé ìwọ kì írí i, ọ̀rọ̀ ìdájọ́, ń bẹ níwájú rẹ,ẹni tí ìwọ sì gbọdọ̀ dúró dè.

15 Ṣùgbọ́n nísinsìnyí nítorí tí ìbínúrẹ̀ kò tí ṣẹ́ ọ níṣẹ̀ẹ́, òun kò ha lèhun ímọ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwà búrubú bí?

16 Nítorí náà ní Jóòbù se ya ẹnu rẹ̀lásán ó ṣọ ọ̀rọ̀ di púpọ̀ láìsí ìmọ̀.”