Jóòbù 17 BMY

Ìdáhùn Jóòbù

1 “Ẹ̀mí mi bàjẹ́,ọjọ́ mi ni a tigé kúrú, ìsà òkú dúró dè mí.

2 Nítòótọ́ àwọn ẹlẹ́yà h wà lọ́dọ̀ mi,ojú mi sì tẹ̀mọ́ ìmúnibínú wọn.

3 “Ǹjẹ́ nísinsínyí, fi lélẹ̀ yàn onígbọ̀wọ́fún mi lọ́dọ̀ rẹ; ta ni Olúwa tí yóò le ṣe ààbò fún mi?

4 Nítorí pé ìwọ ti ṣé wọ́n láyà kúrònínú òyè; nítorí náà ìwọ kì yóò gbé wọn lékè.

5 Ẹni tí ó fi àwọn ọ̀rẹ́ hàn fúnìgárá, òun ni ojú àwọn ọmọ rẹ̀ yóò mú òfo.

6 “Ọlọ́run ti sọ mi di ẹni òwe fúnàwọn ènìyàn; níwájú wọn ni mo dàbí ẹni ìtutọ́ sí ní ojú.

7 Ojú mí ṣú bàìbàì nítorí ìbìnújẹ́,gbogbo ẹ̀yà ara mi sì dàbí òjìji.

8 Àwọn olódodo yóò yanu sí èyí,ẹni aláìsẹ̀ sì bínú sí àwọn àgàbàgebè.

9 Olódodo pẹ̀lú yóò di ọ̀nà rẹ̀ mú,àti ọlọ́wọ́ mímì yóò máa lera síwájú.

10 “Ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti gbogbo yín, ẹ yípadà, kí ẹ sì tún bọ̀ nísinsin yìí;èmi kò le rí ọlọgbọ́n kan nínú yín.

11 Ọjọ́ tí èmi ti kọjá, ìro mi ti fàjá, àní ìro ọkàn mi.

12 Àwọn ènìyàn wọn yí ìsọ́ òru diọ̀sán; wọ́n ní, ìmọ́lẹ̀ súnmọ́ ibi tí òkùnkùn dé.

13 Bí mo tilẹ̀ ní ìrètí, ipò òku ní ilémi; mo ti tẹ́ ìbùsùn mi sínú òkùnkùn.

14 Èmi ti wí fún ìdibàjẹ́ pé, ìwọ nibaba mi, àti fún kòkòrò pé,ìwọ ni ìyá mi àti arábìnrin mi,

15 Ìrètí mi ha dà nísinsinyí? Bí ó ṣeti ìrètí mi ni, ta ni yóò rí i?

16 Yóò sọ̀kalẹ̀ lọ sínú ipò òkú,nígbà tí a jùmọ̀ sinmi pọ̀ nínú erùpẹ̀ ilẹ̀?”