Jóòbù 5 BMY

Ìjìyà Jẹ́ Èṣo Àìṣòdodo

1 “Ó jẹ́ pé nísinsìn yìí bí ẹnìkan bá wà tí yóò dá wa lóhùn?Tàbí ta ni nínú àwọn ènìyàn mímọ́ tí ìwọ ó wò?

2 Nítorí pé ìbínú pa aláìmòye,ìrunú a sì pa òpè ènìyàn.

3 Èmi ti rí aláìmòye ti ó ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n lulẹ̀,ṣùgbọ́n lójú kan náà mo fi ibùjókòó rẹ̀ bú.

4 Àwọn ọmọ rẹ̀ kò jìnnà sí ewu,a sì tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ lójú ibodè,bẹ́ẹ̀ ni kò sí aláàbò kan.

5 Ìkórè oko ẹni tí àwọn tí ebi ń pa jẹẹran, tí wọ́n sì wọ inú ẹ̀kún lọ kó,àwọn ìgárá sì gbé ohun ìní wọn mì.

6 Bí ìpọ́njú kò bá ti inú erùpẹ̀ jáde wá ni,tí ìyọnu kò ti ilẹ̀ jáde wá.

7 Ṣùgbọ́n a bí ènìyàn sínú wàhálà,gẹ́gẹ́ bí ìpẹ́pẹ́ iná ti máa ń ta sókè.

8 “Sọ́dọ̀ Ọlọ́run ní èmi lè máa ṣe àwárí,ní ọwọ́ Ọlọ́run ní èmi lè máa fi ọ̀rọ̀ mi lé.

9 Ẹni tí ó ṣe ohun tí ó tóbi tí a kò lè ṣe àwárí,ohun ìyanu láìní iye.

10 Tí ń rọ̀jò sí orí ilẹ̀ ayétí ó sì ń rán omi sí ilẹ̀ẹ́lẹ̀.

11 Láti gbé àwọn orilẹ̀ èdè lékèkí á lè gbé àwọn ẹni ìbànújẹ́ ga sí ibi aláìléwu.

12 Ó yí ìmọ̀ àwọn alárèékérekè po,bẹ́ẹ̀ ní ọwọ́ wọn kò lè mú ìdàwọ́lé wọn sẹ.

13 Ó mú àwọn ọlọ́gbọ́n nínú arékerekè ara wọn,àti ìmọ̀ àwọn òǹrorò ní ó tari ṣubú ní ògèdèǹgbé.

14 Wọ́n sáre wọ inú òkùnkùn ní ọ̀sánwọ́n sì fọwọ́ tálẹ̀ ní ọ̀sán gangan bí ẹni pé ní òru.

15 Ṣùgbọ́n ó gba talákà là ní ọwọ́ idà,lọ́wọ́ ẹnu wọn àti lọ́wọ́ àwọn alágbára.

16 Bẹ́ẹ̀ ni ìrètí wà fún talákààìsòótọ́ sì pa ẹnu rẹ̀ mọ́.

17 “Kíyèsíi, ìbùkún ni fún ẹni tí Ọlọ́run bá wí,nítorí náà, má ṣe gan ìbàwí Olódùmarè.

18 Nítorí pé òun a mú ni lára kan,a sì di ìdì ìtura, ó ṣá lọ́gbẹ́, ọwọ́ rẹ̀ á sì mú jìnnà.

19 Yóò gbà ọ́ nínú ìpọ́njú mẹ́fà,àní nínú méje, ibi kan kì yóò bá ọ

20 Nínu ìyànu yóò gbà ọ́ lọ́wọ́ ikúàti nínú ogun, yóò gbà ọ́ lọ́wọ́ idà.

21 A ó pa ọ́ mọ́ kúrò lọ́wọ́ iná ahọ́nbẹ́ẹ̀ ní ìwọ kì yóò bẹ̀rù ìparun tí ó bá dé.

22 Ìrin ìparun àti ti ìyàn ni ìwọ yóò rìnbẹ́ẹ̀ ni ìwọ kì yóò bẹ̀rù ẹranko ilẹ̀ ayé.

23 Nitorí pé ìwọ ó bá òkúta ìgbẹ́ múlẹ̀,àwọn ẹranko ìgbẹ́ yóò wà pẹ̀lú rẹ ní àlàáfíà.

24 Ìwọ ó sì mọ̀ pé àlàáfíà ni ibùjókòó rẹ wàìwọ yóò sì máa ṣe ìbẹ̀wò ibùjókòó rẹ, ìwọ kì yóò sìnà.

25 Ìwọ ó sì mọ̀ pẹ̀lú pé irú ọmọ rẹ ó sì pọ̀àti àwọn ọmọ ọmọ rẹ yóò rí bí koríko ìgbẹ́.

26 Ìwọ yóò wọ iṣà òkú rẹ ní ògbólógbòó ọjọ́,bí àpò-ọkà tí ó gbó tí á sì kó ní ìgbà ìkórè rẹ̀.

27 “Kíyèsí i, àwa ti wádìí rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ní ó rí!Gbà á gbọ́, kí o sì mọ̀ pé fún ire ara rẹ ni.”