Jóòbù 32 BMY

Ọ̀rọ̀ Élíhù

1 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọkùnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí dákẹ́ láti dá Jóòbù lóhùn, nítorí ó ṣe olódodo lójú ara rẹ̀.

2 Nígbà náà ni inú bí Élíhù ọmọ Bárákélì ará Búsì, láti ìbátan ìdílé Rámù; ó bínú si Jóòbù nítorí ti ó dá ara rẹ̀ láre kàkà ki ó dá Ọlọ́run láre.

3 Inú sì bí i sí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, nítorí tí wọn kò rí ọ̀nà láti dá Jóòbù lóhùn bẹ́ẹ̀ ni wọ́n dá Jóòbù lẹ́bi.

4 Ǹjẹ́ Élihù ti dúró tití Jóòbù fi sọ̀rọ̀ tán nitorí tí àwọn wọ̀nyí dàgbà ju òun lọ ní iye ọjọ́.

5 Nígbà tí Élíhù ríi pé ìdáhùn ọ̀rọ̀ kò sí ní ẹnu àwọn ọkùnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí nígbà náà ni ó bínú.

6 Élíhù, ọmọ Bárákélì, ará Búsì,dáhùn ó sì wí pé: ọmọdé ní èmiàgbà sì ní ẹ̀yin; Ǹjẹ́ nítorí náàní mo dúró mo sì ń bẹ̀rù láti fiìmọ̀ mi hàn yin.

7 Èmi wí pé ọjọjọ́ ni ìbá sọ̀rọ̀, àtiọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ní ìbá kọ́ ni ní ọgbọ́n.

8 Ṣùgbọ́n ẹ̀mi kan ní ó wà nínúènìyàn àti ìmísí Olódùmarè ní ì sì máa fún wọn ní òye.

9 Ènìyàn ńláńlá kì íṣe ọlọ́gbọ́n,Bẹ́ẹ̀ ni àwọn àgbà ní òye ẹ̀tọ́ kò yé.

10 “Nítorí náà ní èmí ṣe wí pé: Ẹ dẹtí sílẹ̀ sí mi;èmí pẹ̀lú yóò fi ìmọ̀ mi hàn.

11 Kíyèsí i, èmí ti dúró de ọ̀rọ̀ yín;Èmi fetísí àròyé yín, nígbà tíẹ̀yin ń wá ọ̀rọ̀ ti ẹ̀nyín yóò sọ;

12 Àní mo fíyèsí yín tinútinú; sìkíyèsí i, kò sí ẹnìkan nínú yín tí ó le já Jóòbù ní irọ́, tàbí tí ó lèdá a lóhùn àríyànjiyàn rẹ̀!

13 Kí ẹ̀yín kí ó má ṣe wí pé, àwa wáọgbọ́n ní àwárí: Ọlọ́run ni ó lè bì í ṣubú, kì í ṣe ènìyàn.

14 Bí òun kò ti sọ̀rọ̀ sí mi, bẹ́ẹ̀ni èmí kì yóò fi ọ̀rọ̀ yín dá a lóhùn.

15 “Ẹnu sì yà wọ́n, wọn kò sì dáhùnmọ́, wọ́n síwọ́ ọ̀rọ̀ ísọ́.

16 Mo si reti, nítorí wọn kò sìfọhún, wọ́n dákẹ́ jẹ́ẹ́; wọn kò sì dáhùn mọ́.

17 Bẹ́ẹ̀ ni èmí ò sì dáhùn nípa tièmí, èmí pẹ̀lú yóò sì fi ìmọ̀ mi hàn.

18 Nítorí pé èmí kún fún ọ̀rọ̀ sísọ,èmí ń rọ̀ mi ni inú mi.

19 Kíyèsí i, ìkùn mi dàbí ọtí wáìnì,tí kò ní ojú-ìhò; ó múra tán láti bẹ́ bí ìgò-àwọ̀ tuntun.

20 Èmí ó sọ, kí ara kí ó le rọ̀ mí,èmí ó sí ètè mi, èmí ó sì dáhùn.

21 Lótítọ́ èmí kì yóò ṣe ojúṣàájú síẹnìkankan, bẹ́ẹ̀ ni èmí kì yóò sì ṣe ìpọ́nni fún ẹnìkan.

22 Nítorí pé èmí kò mọ̀ ọ̀rọ̀ ìpọ́nni í sọ;ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀, Ẹlẹ́dàá mi yóò mú mi kúrò lọ́gán.