Jóòbù 23 BMY

Èsì Jóòbù

1 Ígbà náà ni Jóòbù sì dáhùn wí pé:

2 “Àní lónìí ni ọ̀ràn mi korò; ọwọ́mí sì wúwo sí ìkérora mi.

3 Áà! èmi ìbá mọ ibi tí èmí ìbá wáỌlọ́run rí, kí èmí kí ó tọ̀ ọ́ lọ sí ibùgbé rẹ̀!

4 Èmi ibá sì to ọ̀ràn náà níwájú rẹ̀,ẹnu mi ìbá sì kún fún àròyé.

5 Èmi ìbá sì mọ ọ̀rọ̀ tí òun ìbá fi dámi lóhùn; òye ohun tí ìbá wí a sì yé mi.

6 Yóò ha fi agbára ńlá bá mi wíjọ́ bí?Àgbẹdọ̀, kìkì pé òun yóò sì kíyèsí mi.

7 Níbẹ̀ ni olódodo le è bá awíjọ́, níwájú rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni èmi yóòsì bọ́ ni ọwọ́ onídájọ́ mi láéláé.

8 “Sì wòó, bí èmi bá lọ sí iwájú,òun kò sí níbẹ̀, àti sí ẹ̀yìn, èmi kò sì rí òye rẹ̀:

9 Ni apá òsì bí ó bá ṣiṣẹ́ níbẹ̀, èmikò rí i, ó fi ara rẹ̀ pamọ́ ni apaọ̀tún, tí èmi kò le è rí i.

10 Ṣùgbọ́n òun mọ ọ̀nà tí èmi ń tọ̀,nígbà tí ó bá dán mí wò, èmi yóò jáde bí wúrà.

11 Ẹṣẹ̀ mí ti tẹ̀lé ipaṣẹ̀ ìrìn rẹ̀; ọ̀nàrẹ̀ ni mo ti kíyèsí, tí ń kò sì yà kúrò.

12 Bẹ́ẹ̀ ni èmi kò padà sẹ́yìn kúrònínú òfin ẹ̀nu rẹ̀, èmi sì pa ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ mọ́ ju oúnjẹ òòjọ́ lọ

13 “Ṣùgbọ́n onínú kan ni òun, ta niyóò sì yí i padà? Èyí tí ọkàn rẹ̀ sì ti fẹ́, èyí náà ní í ṣe.

14 Nítòótọ́ ohun tí a ti yàn fún mi níí ṣe; ọ̀pọ̀lọpọ̀ irú bẹ́ẹ̀ ni ó wà ní ọwọ́ rẹ̀.

15 Nítorí náà ni ara kò ṣe rọ̀ míníwájú rẹ̀; nígbà tí mo bá rò ó, ẹ̀rù a bà mi.

16 Nítorí pé Ọlọ́run ti pá mi ní àyà,Olodùmáarè sì ń dààmú mi,

17 Nítorí tí a kò tí ì ké mi kúròníwájú òkùnkùn, bẹ́ẹ̀ ni kò paòkùnkùn biribiri mọ́ kúrò níwájú mi.