Jóòbù 36 BMY

1 Elíhù sì tún sọ̀rọ̀ wí pé:

2 “Fún mi láyè díẹ̀ èmi ó sì fi hàn ọ́nítorí ọ̀rọ̀ sísọ ní ó kún fún Ọlọ́run.

3 Èmi ó mú ìmọ̀ mi ti ọ̀nà jínjìn wá,èmi ó sì fi òdodo fún Ẹlẹ́dàá mi.

4 Rí i dájú pé ọ̀rọ̀ mi kì yóò ṣèkénítòótọ́; ẹni tí ó pé ní ìmọ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀.

5 “Kíyèsí i, Ọlọ́run ni alágbára, kò sìgàn ènìyàn; ó ní agbára ní ipá àti òye.

6 Òun kì í dá ẹ̀mí ènìyàn búburú síṣùgbọ́n ó fi òtítọ́ fún àwọn tálákà.

7 Òun kì ímú ojú rẹ̀ kúrò lára olódodo,ṣùgbọ́n àwọn ọba ni wọ́nwà lórí ìtẹ́; Àní ó fi ìdí wọn múlẹ̀ láéláé, a sì gbé wọn lékè.

8 Bí ó bá sì dè wọ́n nínú àbà, tí asì fi okùn ìpọ́njú dè wọ́n,

9 Nígbà náà ni o ń sọ àwọn ohun tíwọn ti ṣe fún wọn, wí pé wọ́n ti ṣẹ̀ pẹ́lú ìgbéraga wọn.

10 Ó sí wọn létí pẹ̀lú sí ọ̀nà ẹ̀kọ́, ósì pàṣẹ kí wọn kí ó padà kúrò nínú àìṣedéédéé.

11 Bí wọ́n bá gbàgbọ́ tí wọ́n sì sìn ín,wọn ó lo ọjọ́ wọn ní ìrọ̀ra, àti ọdún wọn nínú afẹ́.

12 Ṣùgbọ́n, bí wọn kò bá gbàgbọ́,wọ́n ó ti ọwọ́ idà ṣègbé, wọ́n á sì kú láìní òye.

13 “Ṣùgbọ́n àwọn àgàbàgebè ní àyékó ìbínú jọ; wọn kò kígbe fún ìrànlọ́wọ́ nígbà tí ó bá dà wọ́n.

14 Nígbà náà ni ọkàn wọn yóò kú níèwe, ẹ̀mí wọn a sì wà nínú àwọn oníwà Sódómù.

15 Òun gba òtòsì nínú ìpọ́njú wọn,a sì sọ̀rọ̀ sí wọn ní etí nínu ìnira wọn.

16 “Bẹ́ẹ̀ ni pẹ̀lúpẹ̀lú ó sì dè ọ lọ látiinú ìhágágá síbi gbòòrò, sí ibi tí ó ní ààyè tí kò ní wàhálànínú rẹ̀ ohun tí a sì gbé kalẹ̀ ní tábìlì rẹ̀ a jẹ́ kìkì ọ̀rá oúnjẹ tí ó fẹ́.

17 Ṣùgbọ́n ìwọ kún fún ìdájọ́ àwọnbúburú; ìdájọ́ àti òtítọ́ dì ọ́ mú.

18 Nítorí ìbínú ń bẹ, ṣọ́ra kí òtítọ́ rẹmáa bàà tàn ọ́; láti jẹ́ kí títóbi èyà mú ọ sìnà.

19 Ọ̀rọ̀ rẹ pọ̀ tó, tí wàhálà kì yóò fidé bá ọ bí? Tàbi ipa agbára rẹ?

20 Má ṣe ìfẹ́ òru, nígbà tí a ń kéàwọn orilẹ̀ èdè kúrò ní ipò wọn.

21 Máa sọra kí ìwọ ki ó má yí ara rẹ̀padà sí búrubú; Nítori èyí tí ìwọ rò pé ó dára jù ìpọ́njú lọ.

22 “Kíyèsí i, Ọlọ́run á gbé-ni-ga nípaagbára rẹ̀; ta ni jẹ́ olùkọ́ni bí òun?

23 Ta ni ó là ọ̀nà iṣẹ́ rẹ̀ sílẹ̀ fún un,tàbí ta ni ó lè wí pé ìwọ ti ń ṣe àìṣedéédéé?

24 Rántí kí ìwọ kí ó gbé iṣẹ́ rẹ̀ ga,ti ènìyàn ni yín nínú orin.

25 Olúkúlùkù a máa rí i; ènìyàn amáa wòó ní òkèrè,

26 Kíyèsí i, Ọlọ́run tóbi, àwa kò sìmọ̀ bí ó ti ní òye tó, bẹ́ẹ̀ ni a kò lè wádìí iye ọdún rẹ̀ rí.

27 “Nítorí pé òun ni ó fa ìkán omiọjọ́ sílẹ̀, kí wọn kí ó kán bí òjò ní odò,

28 tí àwọsánmọ̀ ń rọ̀, tí ó sì fi ńgbìn lọ́pọ̀lọpọ̀ lórí ènìyàn.

29 Pẹ̀lúpẹ̀lú ẹnikẹ́ni lè imọ́ ìtànkáàwọ̀sánmọ̀, tàbí ariwo àrá láti àgọ́ rẹ̀?

30 Kíyèsí i, ó tan ìmọ́lẹ̀ yí ara rẹ̀ká ó sì bo ìsàlẹ̀ òkun mọ́lẹ̀.

31 Nitorí pé nípa wọn ní ń ṣe dájọ́àwọn orílè èdè ènìyàn; ó sí ń pèsè oúnjẹ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀.

32 Ó fi ìmọ́lẹ̀ bo ọwọ́ rẹ̀ méjèèje ó sìrán sí ẹni olódì.

33 Ariwo àrá rẹ̀ fi ìjì hàn ní; ọ̀wọ́ẹran pẹ̀lú wí pé, ó súnmọ́ etílé!