Jóòbù 39 BMY

Agbára Ọlọ́run

1 “Ìwọ mọ àkókò ìgbà tíàwọn ewúrẹ́ orí àpáta ìbímọ? Ìwọsì lè kíyèsí ìgbà tí abo àgbọ̀nrín ń bímọ?

2 Ìwọ lè ka iye òṣùpá tí wọn ń pè,ìwọ sì mọ àkókò ìgbà tí wọn ń bímọ,

3 Wọ́n tẹ ara wọn ba, wọ́n bí mọ,wọ́n sì mú ìkáànú wọn jáde.

4 Àwọn ọmọ wọn rí dáradára, wọ́ndàgbà nínú ọ̀dàn; wọ́n jáde lọ, wọn kò sì tún padà wá sọ́dọ̀ wọn.

5 “Ta ni ó jọ̀wọ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ oko lọ́wọ́?Tàbí ta ní ó tú ìdè kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ìgbẹ́,

6 Èyí tí mo fi ihà ṣe ilé fún, àtiilẹ̀ iyọ̀ ní ibùgbé rẹ̀

7 Ó rẹ́rìnín sí ariwo ìlú, bẹ́ẹ̀ niÒun kò sì gbọ́ igbe darandaran.

8 Orí àtòlé òkè ńlá ni ibùjókòó rẹ̀,Òun asì má a wá ewé tútù gbogbo rí.

9 “Àgbáǹréré ha jẹ́ sìn ọ́ bí? Tàbí,ó jẹ́ dúró ní ibùjẹ ẹran rẹ ní òru?

10 Ìwọ le fi òkò tata de àgbáǹrérénínú aporo? Tàbí ó jẹ́ máa faìtulẹ̀ nínú aporo oko tọ̀ ọ́ lẹ́yìn?

11 Ìwọ ó gbẹ́kẹ̀ lée nítorí agbára rẹ̀pọ̀ ìwọ ó sì fi iṣẹ́ rẹ lé e lọ́wọ́?

12 Ìwọ le gbẹ́kẹ̀ le pé, yóò mú èsooko rẹ̀ wá sílé, àti pé yóò sì kó ọ jọ sínu àká rẹ?

13 “Ìyẹ́ abo ògòǹgò ń fi ayọ̀ fì;Ṣùgbọ́n a kò le fi àká we ara wọn ní ìyẹ́ àti ìhùhù

14 Ó yé ẹ̀yìn rẹ̀ sílẹ̀ lórí ilẹ̀,a sì mú wọn gbóná nínú ekuru;

15 Tí ó sì gbàgbé pé, ẹ̀sẹ̀ lè tẹ̀ wọ́nfọ́, tàbí pé ẹranko ìgbẹ́ lè tẹ̀ wọ́n fọ́.

16 Kò ní àánú sí àwọn ọmọ rẹ̀ bíẹni pé wọn kì í ṣe tirẹ̀; asán ni iṣẹ́ rẹ̀, láì ní ìbẹ̀rù;

17 Nítorí pé Ọlọ́run kò fún-un ní ọgbọ́n,bẹ́ẹ̀ ni kò sì fi ìpín òye fún un.

18 Nígbà tí ó gbé ara sókè, ó ganẹṣin àti ẹlẹ́ṣin.

19 “Ìwọ ni ó fi agbára fún ẹṣin bí? tàbí ṣéÌwọ ni ó fi gọ̀gọ̀ wọ ọrùn rẹ̀ ní aṣọ?

20 Ìwọ le mú fò sókè bí ẹlẹ́ǹgà?Ògo èémí imú rẹ ní ẹ̀rù ńlá;

21 Ó fi ẹsẹ̀ halẹ̀ nínú àfonífojì, ó sì yọ̀ síagbára rẹ̀; ó lọ jáde láti pàdé àwọn ìhámọ́ra ogun.

22 Ó fi ojú kékeré wo ẹ̀rù, àyà kòsì fòó; bẹ́ẹ̀ ni kì í sì í padà ṣẹ́yìn kúrò lọ́wọ́ idà.

23 Lọ́dọ̀ rẹ ni apó-ọfà ń mìpẹ́kẹ́pẹ́kẹ́, àti ọ̀kọ̀ dídán àti àpáta.

24 Ó fi kíkorò ojú àti ìbínú ńlá gbéilẹ̀ mì, bẹ́ẹ̀ ni òun kò sì gbàá gbọ́ pé, ìró ipè ni.

25 Ó wí nígbà ìpè pé, Háà! Háà!Ó sì gbóhùn ogun lókè réré, araàwọn balógun àti ariwo ogun wọn.

26 “Àwòdì ha máa ti ipa ọgbọ́n rẹ̀ fòsókè tí ó sì mọ ìyẹ́ apá rẹ̀ sí ìhà gúsù?

27 Idì ha máa fi àṣẹ rẹ̀ fò sókè kí ósì lọ tẹ́ ìtẹ́ rẹ̀ sí òkè gíga?

28 Ó ń gbé, ó sì ń wò ní orí àpáta,lórí pàlàpálá òkúta àti ibi orí òkè.

29 Láti ibẹ̀ lọ ni ó ti ń wá oúnjẹ́kiri, ojú rẹ̀ sì ríran rí òkè réré.

30 Àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú a máa mu ẹ̀jẹ̀,níbi tí òkú bá gbé wà, níbẹ̀ ni òun wà pẹ̀lú.”