Jóòbù 12 BMY

Ìdáhùn Jóòbù

1 Jóòbù sì dáhùn, ó sì wí pé:

2 “Kò sí àní-àní níbẹ̀,ṣùgbọ́n ẹ̀yin ni àwọn ènìyàn náà,ọgbọ́n yóò sì kú pẹ̀lú yín!

3 Ṣùgbọ́n èmi ní ìyè nínú gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin:èmi kò rẹ̀yìn sí i yín:àní, ta ni kò mọ gbogbo nǹkan wọ̀nyí?

4 “Èmi dàbí ẹni tí a ń fi ṣe ẹlẹ́yà lọ́dọ̀ aládùúgbò rẹ̀,tí ó ké pe Ọlọ́run, tí ó sì dá a lóhùn:à ń fi olóòótọ́ ẹni-ìdúró-ṣinṣin rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà.

5 Ẹ̀gàn ni ẹni-ò-tòsì,tí ẹsẹ̀ rẹ múra tan láti yọ, nínú ìró ẹni tí ara rọ̀.

6 Àgọ́ àwọn ìgárá ń bẹ̀rù;àwọn tí ó sì ń mú Ọlọ́run bínú wà láìléwu,àwọn ẹni tí ó sì gbá òrìṣà mú ní ọwọ́ wọn.

7 “Ṣùgbọ́n nísínyìí bí àwọn ẹranko léèrè, wọn o kọ́ ọ ní ẹ̀kọ́,àti ẹyẹ ojú ọ̀run, wọn ó sì sọ fún ọ.

8 Tàbí ba ilẹ̀ àyé sọ̀rọ̀, yóò sì kọ́ ọ,àwọn ẹja inú òkun yóò sì sọ fún ọ.

9 Ta ni kò mọ̀ nínú gbogbo nǹkanwọ̀nyí pé, ọwọ́ Olúwa ni ó ṣe nǹkan yìí?

10 Ní ọwọ́ ẹni tí ẹ̀mí ohun alààyègbogbo gbé wà, Àti ẹ̀mí gbogbo aráyé.

11 Etí kì í dán ọ̀rọ̀ wò bí, Tàbí adùnẹnu kì í sì í tọ́ oúnjẹ rẹ̀ wò bí?

12 Àwọn arúgbó ni ọgbọ́n wà fún,Àti nínú gígùn ọjọ́ ni òye?

13 “Pẹ̀lú rẹ Ọlọ́run ni ọgbọ́n àti agbára:Òun ni ìmọ̀ àti òye.

14 Kíyèsí i, ó bì wó, a kò sì lè gberó mọ́;Ó ṣé ènìyàn mọ́, kò sì sí ìsísílẹ̀ kan.

15 Kíyèsí i, ó dá àwọn omi dúró,wọ́n sì gbẹ; Ó sì rán wọn jáde, wọ́n sì sẹ̀ bo ilẹ̀ ayé yípo.

16 Pẹ̀lú rẹ ni agbára àti ìṣẹ́gun;Ẹni tí ń sìnà àti ẹni tí ń mú ni sìnà, tirẹ̀ ni wọ́n ń ṣe.

17 Ó mú àwọn ìgbìmọ̀ lọ ní ìhòòhò,A sì sọ àwọn onídàájọ́ di òmùgọ̀.

18 Ó tú ìdè ọba,Ó sì fi mú àmùrè gbà wọ́n ní ọ̀já.

19 Ó mú àwọn àlùfáà lọ ní ìhòòhò,Ó sì tẹ orí àwọn alágbára ba.

20 Ó mú ọ̀rọ̀ ẹnu ẹni ìgbẹ́kẹ̀lé kúrò,Ó sì ra àwọn àgbààgbà ní iyè.

21 Ó bu ẹ̀gàn lu àwọn ọmọ ọlọ́là,Ó sì tú àmùrè àwọn alágbára.

22 Ó hú ìdí ohun ìjìnlẹ̀ jáde láti inú òkùnkùn wá,Ó sì mú òjìji ikú wá sínú ìmọ́lẹ̀.

23 Òun a mú orílẹ̀-èdè bí sí i, a sì run wọ́n;Òun a sọ orílẹ̀-èdè di ńlá, a sì tún ṣẹ̀ wọn kù.

24 Òun a gba àyà olú àwọn ènìyàn aráyé,A sì máa mú wọn wọ́ kiri nínú ijù níbi tí ọ̀nà kò sí.

25 Wọn a máa fi ọwọ́ ta ilẹ̀ nínú òkùnkùn níbi tí kò sí ìmọ́lẹ̀,Òun a sì máa mú wọn tàsé ìrìn bí ọ̀mùtí.